Won ti gbe Sergio Aguero omo egbe agbaboolu Argentina lo si ile iwosan ni igba to daku leyin idije to waye lana laarin Super Eagles ti Nigeria ati Argentina nibi ti won ti je omi ayo merin si meji.

Awon oniwosan ati awon ton se itoju awon agbaboolu, lana gbe Sergio Aguero lo si ile iwosan kan to wa ni orilede Russia leyin igba ti arakunrin na daku ninu yara iwoso ni orilede na.
Ogbeni Jorge Sampaoli eni to je alamojuto awon agbaboolu na se, o so wipe O re arakunrin Sergio ni, o si daku, sugbon o ti pada bo si ipo bayi, o si ti wa ni ile itura pelu awon akegbe re.

Comments