ORIKI NI ILE YORUBA.

Oriki je asa kan ti o je iran Yoruba l’ogun pupo, eyi si mu won yato si awon iran yoku patapata, ko si ojulowo omo kaaro- o- o- jiire , ti ko ni oriki, yala oriki orile ni tabi oriki idile ati paapaa oriki oruko.Oriki je awon oro isiri ti awon Yoruba maa n fi yin ara won tabi eni ti inu won ba dun si.


Orisirisi iran ti won maa n ki ojulowo omo Yoruba mo niwonyi; iran Alaran, Aagberi, Olu-oje, Osulakesan, Ijamogbo, Onikoyi, Oko irese, Ajisola, Ologbin-in, Opomulero, Olofa, Olokun-Esin, Olufe, Elerin, Ijese, Iloko, Orin, Aresa.
Oriki orile ni ewi alohun ti o n so nipa itan awon baba nla eni ni ile Yoruba, idile ti won ti se wa,orirun iran, ise akin ti won ti gbe ile aye se, ise iran naa ati beebee lo.


Oriki idile a maa so nipa irisi iran, isesi, eewo iran, ise iran, aleebu iran ati beebee lo.


Oruko oriki ni oruko keji ti awon Yoruba maa n fun omo ni ojo isomoloruko yala okunrin tabi obinrin bi apeere;
Ajoke, Amope, Isola, Atoke, Ajao, Arike, Abike, Ajani .Aimoye awon omo wa in won ko ni oruko oriki mo ti kosi daara.


Daruko orike re .


Bv Olori Orente

Comments

Post a Comment