Awon agbebon kan ti yin ibon pa Rasaq Bello oga agba NURTW ni Oshodi.

Ogbeni Rasaq Bello eniti gbogbo eyan mon si Hamburger ni awon agbebon kan ti yin ibon pa ni agbegbe Shogunle ni Oshodi ipinle Eko. Isele na sele nigba ti awon egbe oloselu APC n se ipade won lowo ti idarudapo si be yo laarin won.
Iwadi fi ye wa wipe awon omo egbe alatako egbe ti Hamburger wa, ti Ogbeni Samson Agbetoye eniti gbogbo eyan mon si Golden dari ni o se iku pa arakunrin na.
Rogbodiyan ti be sile latari iku Rasaq eyi to si ti fa ti won fi ti oja Ladipo pa, opolopo oko ati dukia olowo iyebiye ni won ti baje. Awon agbofinro ti wa lo si adugbo na lati se iwadi, ki won je ki alafia o pada si adugbo na.

Comments