Owo awon agbofinro ti ba awon adigunjale kan ni ipinle Benue.

Owo awon ogbofinro ti Zenda special crack squad ni ipinle Benue ti ba awon odaran merin kan ni ilu Adamgbe Tse-lyssa ni opopona Benue si Taraba. Oruko awon odaran na ton je Saayua Abashed, Isaac Usafa, Godwin Terlumun, ati Aondohemba Abum, ni iwadi fi han wipe won tin gbero lati lo digun jale ni oja Zaki-Biam lai pe ojo. Orisirisi awon oun ija oloro ni won ri gba lowo won bi ibon AK47, ibon shakabula, ibon ilewo, opolopo ota, ada, ibon ati ake.
 Awon agbofinro ti bere iwadi to peye lori oro won ti won si ti setan lati gbe won lo si ile ejo.

Comments