Ijamaba oko to waye ni irole oni ni agbegbe Felele ni ilu Lokoja ni ipinle Kogi ni awon eyan mewa o kere tan ti jona guru-guru, ti opolopo awon eyan si farapa yana-yana. Awon osise ajo FRSC so wipe isele na sele nigbati oko ajagbe agbepo (Petrol tanker) kan fi ori so oko akero kan ni opopona Lokoja si Abuja.
Awon eleso abo ilu ti ko oku awon to jona na lo si ile igboku si, ti awon to farapa si tin gba itoju to peye ni ile iwosan ijoba to wa ni ilu Lokoja.
Comments
Post a Comment