Awon ogbontarigi ajinigbe meta ti oruko won nje Mohammed Abdulrazak, Yusuf Abona Jafaru ati Iliyasu Yusuf Nyamida ni awon olopa ton soju ipinle Kogi ti mu.
Gege bi atejade ti oga olopa ton soju ipinle na Wilson Inalegwu se, o so wipe ni ogbon ojo osu kejo ni awon agbofinro da oko Gulf Station Wagon kan duro ni opopona okene, sugbon awako na ko lati duro. Eyi lo fa ti awon agbofinro na fi fi oko tiwon le oko na ti won si ri won mu.
Igba ti won mu won tan, ti won si tu inu oko won ni won ri orisirisi nkan ija oloro bi ibon, ada ati ogun.
Awon olopa ti tesi waju lati gbe won lo si ago won, to wa ni ilu okene, ti won si ti setan lati gbe won lo si ile ejo.
Comments
Post a Comment