Oga olopa kan gbemi ara re, leyi igba to pa oga re nitori abetele ni ipinle Ondo.

Ogbeni Abraham Arowogun, oga olopa kan to soju ago olopa to wa ni Kajola ni ijoba ipinle Odigbo ni ipinle Ondo, lo yin ibon pa oga re  Timothy Arueli. Isele na sele nigba ti awo be le laarin awon oga olopa mejeji nitori abetele owo to to 150 naira.
Timothy lo ti kilo fun Arowogun wipe ko lo da abetele to gba lowo enikan pada fun, eyi lo bi Arowogun ninu, to si mu ibon, to si yin oga re pa. Leyin igba to se eleyi, lo ri wipe oun ti se asise, o sare jade kuro ninu ago olopa na, o si lo fo sinu konga to wa ninu agbegbe ago olopa na.
Isele kayefi ni eyi je, to si ya gbogbo awon akegbe won lenu.
Oku awon mejeji yi ni won ti gbe lo ile igboku si to wa ni ipinle Ondo.

Comments