Awon agbofinro mu arakunrin kan ni ipinle Ekiti fun esun ifipa-banilo (rape).

Awon olopa ipinle Ekiti ti mu arakunrin kan ti oruko re n je Tope, awako kan ni ipinle Ekiti fun esun ifipa-banilo. Gege bi iwadi ti awon olopa se, won so wipe ogbeni Tope lo fi ipa ba odomodebirin omo ile eko giga ti Ekiti sun ni nkan bi ago mejo ale ninu oko re nigbati odomode birin na n bo lati ile iwosan to ti lo gba itoju fun aisan iba.
   Eyi lo wa fa ija laarin awon egbe awako ati awon akeko ni ipinle na. Awon olopa bakan na ti wa mu odaran na, won si ti setan lati gbe lo si ile ejo.

Comments