Awon agbofinro ti mu awon okunrin mesan fun esun adigunjale ati ifipa-banilo ni ipinle Kano.






Awon olopa ton soju ipinle Kano ni ojo kerindinlogun osu yi ni won mu awon adigunjale mesan kan fun esun adigunjale ati ifipa-banilo. Oga olopa DSP Magaji Musa Majia nigba ton ba awon oniroyin soro so wipe awon o ni pada lori ipinu awon lati mu alafia joba ni ipinle na, awon si ti bere si se ise to peye lati ri wipe adinku de ba iwa odaran ni awujo.
   O so siwaju si wipe awon ti pari iwadi lori oro na, awonsi ti setan lati gbe awon odaran na lo, lati lo fi oju ba ile ejo.

Comments