Ijoba ipinle Eko ti yan Adajo Opeyemi Oke gege bi Adajo agba (chief judge) fun ipinle na.

Gomina Akinwunmi Ambode ni osan oni yan se ibura fun Adajo Opeyemi Oke gege bi Adajo agba  fun ipinle na. Gomina na so ninu atejade re wipe yiyan arabirin na tele ilana ati ofin to gbe ise awon adajo ro.  O ki Adajo na ku orire o si gba ni iyanju lati mura si ise re ko si fi ooto okan je ise na, bo ti to ati bo ti ye.

Comments