Awon agbofinro ti mu awon adigunjale meje, won si gba oko merindinlogbon lowo won ni ipinle Ogun.

Awon agbofinro ton soju ipinle Ogun ni ojo kefa osu kewa ti mu awon adigunjale meje nigba ti won fi ipa gba oko ayokele Toyota Camry lowo arakunrin kan ni opopona Sango Otta. Ni oju ese ni awon olopa na ti fi awon odaran meta sinu atimole,ti won si ri awon merin to ku mu nigba ti awon meta na jewo.  Iwadi ti awon agbofinro na se lo je ki won ri wipe oko merindinlogbon ni awon adigunjale na ti ji gbe, pelu opolopo awon dukia.
    Oruko awon adigunjale na ni yi; Joshua Tabiti, Moses Ofoke, Oluseye Arokoyo, Ahmed Alli, Folorunsho Ojowuro, Christopher Mmadike and Samuel Bolala. Awon agbofinro wayi ti wa pinu lati gbe awon odaran na lo, lati fi oju ba ile ejo.

Comments