O ma se o! Baba arugbo kan daku, o si gba ibe ku ni iwaju ile ejo kotemilorun (magistrate court) ni ipinle Eko.

Iyalenu ati ibanuje okan lo je nigba ti awon eyan ri oku baba arugbo yi niwaju ile ejo kotemilorun to wa ni agbegbe Ikeja ni ipinle Eko. Awon ti oro na se oju won so wipe ni se ni baba na daku to si tibe gba orun lo. Awon eleyin ju anu kan ti wa gbinyanju lati pe awon molebi baba na lori ero ibara eni soro, won si ti seto biwon o se gbe oku baba na lo si ile igbokusi.  Adura wa ni wipe ki Olorun fi oriji baba na. Amin.

Comments