ORIKI ILU OSOGBO (The Cognomen Of Osogbo).





Osogbo Oroki Asala Onile Obi
Osogbo ilu Aro, Aro dede bi Okun
Are Op'eta, Are p'eta a gba
Osogbo Oroki gbe Onile o tun gbe Ajeji
Osogbo Oroki Omo yeye Osun
Yeye Atewogbeja Aniyun Labebe
Eleyele Aro, Olode Ega, Ega susu ni yara
Ewure Orangun ti n je lese Gbagede
Lese Gbagede ni ti ije
Aguntan Orangun nii je lese Yara
Akuko gagara t'o rori Ope ree le tente
Nibe ni won ti n pe Alara tantan
Ogboju Obinrin tii fi owo gbogboro yo omo re lofin
Yeye Larooye t'o ti Ipole di onile losogbo
Yeye Timehin akikanju Ode t'o m'erin wa mo ilu Osogbo,
Osogbo Oroki omo Olofin agba Ife
Omo Owa Oluyeye, Omo Obokun
Omo odo kan odo kan ti won n pe losun
Omo atenigbola olodo ide
Ogun kan, Ogun kan ti won n ja loroki ile
Obinrin gbona, Okunrin ko gbodo koja
Bi Okorokoro ti n gba oko niju
Bee ni Ogbaagbaa n run bala bi ose
Opo gbegiri l'osun fi segun Fulani
Ogun ko gbogbo jami, mo gbekeleOsun
Oroki tii ba Eja nla soro, tii ran iko ni'se
Osun Osogbo rere ni'Osun funmi
Ire Owo, Ire Omo, Ire Aiku Baale Oro
Osun t'ori ajigbara, leke o bawon ni orun gigun
O'tori ide wewe o bawon lapa gbogboro
B'oba wu agba Ijesha a san'so si bebere idi
B'oba wu Morokahan a san'so Gbogbo lo itan
Osogbo Oroki t'oni lakokan l'o ni Ohuntofo
Oun loni Ogidan tii fi Odo ide fo'gun
Omo atupa merindinlogun tii tan loroki ile
B'oba tan f'oba a tan f'osun
A tun tan fun irunmole a tan f'eniyan
Osogbo wumi ide ki n lo d'agbala osun
Ni bi ti won ti n re ro ti won tun ti n gundo ide,
A kii b'omi s'ote, a kii b'omi s'ota
Omi l'a buwe, omi la bu mu
Ore yeye Osun Osogbo o.

Comments

Post a Comment