Otunba Gani Adams ti setan lati je oye Aare Ona Kakanfo elekarundinlogun ti ile Yoruba.

Otunba Gani Adams ti setan lati je oye Aare Ona Kankanfo elekarundinlogun ti ile Yoruba ni ojo ketala osu kini odun 2018. Afihan yi waye ninu atejade ti ogbeni Femi Adepoju se ni ana ojo aje. O so siwaju si wipe ifini joye yi lo waye latari yiyan ti Alafin ti OYO yan Otunba Gani Adams ni ojo karundinlogoji osu kewa odun yi.
   O se alaye wipe yiyan ti won yan Otunba Gani Adams wa latari akitiyan re lati ri wipe ede, asa ati ise awon omo Yoruba tunbo gboro si, ki itesiwaju si ba igbeaye awon omo Yoruba lapapo.

Comments