Awon agbebon (gun men) pa ojise Olorun kan ni ipinle Ondo.

Awon agbebon kan ti won fura si wipe ajinigbe niwon  pa ojise olorun kan ti oruko re nje Oluwafemi Komolafe ni opopona Benin si Ijebu Ode ni ilu  Ore ijoba ipinle Odigbo ni ipinle Ondo.Gege bi iwadi, won so wipe ojise Olorun na lon rin irin ajo pelu omo re Timilehin ni ojo kerinlelogun osu yi nigba ti awon odaran na da won lona.
   Oga olopa ipinle Ondo, Gbenga Adeyanju nigba ton ba awon oniroyin soro, lo so wipe awon odaran na lo ti ji Timilehin gbe leyin igba ti won pa Baba re, sugbon awon omo ile ise olopa ipinle na ti se ise takuntakun lati gba omo na kuro lowo won. O so siwaju si wipe awon padanu ikan ninu awon olopa to lo koju awon odaran na, wipe awon si ti gbe oku olopa na pelu ti ojise Olorun na lo si ite igboku si.

Atejade na ni yi ni ede geesi;
“The man (pastor) was travelling with his son when the kidnappers stopped them on the road, they shot the man and took the boy away. Our men engaged the hoodlums in a shootout but they escaped. We even lost one of our men who went for the operation. After the incident, our men with the assistance of the local hunters combed the whole area. We attacked the hoodlums and we were able to rescue the three victims in their den. The boy whose father was killed and two other travellers who were going to Lagos from Port Harcourt were rescued successfully'
The remains of the deceased pastor and police officer has been deposited at the state morgue.

Comments