Ogbeni Anthony Joshua lo gbe igba oroke nigba to fi ajeku iya je akegbe re Joseph Parker ninu idije ese-kikan to waye laarin awon mejeji.
Odomode kunrin amese ku bi ojo Anthony Joshua tun ti gbe igba oroke ninu idije ese kikan to waye laarin re ati ogbeni Joseph Parker ni papa idaraya Principality Stadium, Cardiff.
Nigba ti Joshua n ba awon akoroyin soro, o so wipe ogbontarigi ati akinkanju onija ni ogbeni Parker na sugbon wipe ko si bo se le le to, eran ogun si ni aja nse. Siwaju si, o dupe lowo awon alatileyin re ati awon ololufe re, o si so wipe ogbeni Deontay Wilder ni ohun gbaradi lati ba ja.
Comments
Post a Comment