Ogbeni Omoyele Sowore lo se abewo si Alafin Oyo, Emir Kano ati awon ori ade miran fun igbaradi eto idibo Aare orilede ton bo ni odun 2019
Ogbeni Omoyele Sowore, ikan ninu awon oludije fun ipo Aare orilede Nigeria ninu idibo ton bo lona ni odun 2019, loni lo se atejade kan lati ki awon omo orilede Nigeria ku ifarada ati fun ayeye odun ijoba alagbada ti orilede Nigeria.
O dupe lowo gbogbo awon ololufe ati alatileyin re ku ise ati igbagbo ti won ni ninu ohun, o si ti pinu lati ma ja enikeni kule. O so eleyi nigba to lo be awon ori ade ati awon loba-loba wo, awon ori ade bi Emir ti Kano, Muhammadu Sanusi 11 ati Alafin ti Oyo, Lamidi Olayiwola Adeyemi III ati awon bebe lo.
Ni ipari, o ro gbogbo awon omo orilede Nigeria lati tu yaya- tu yaya jade lati lo gba kadi idibo won, ki won si gbiyanju lati jade dibo ti eto idibo na ba de.
Comments
Post a Comment