Oma se o! Awon omo meji kan so emi won nu ninu ijamba ina to sele ni ipinle Ondo

Ibanuje dori agbakodo nigbati awon omo meji so emi won nu ninu ijamba ina kan to ba opolopo dukia je ni agbegbe Edo Lodge ni ilu Akure ni ipinle Ondo.
Awon ti oro na se oju won so wipe awon omo meji na ti won je tegbon-taburo ni oruko won nje Damilare Omolere ati Itunu. Won fi han wipe ko si awon obi awon omo na nile nigba ti ijamba ina na sele, eyi lo fa ti won o fi ri aye sa jade ninu ile na.
Adura wa ni wipe ki Olorun ma so wa ki a ma si ri apada si aburu. Amin

Comments