Opolopo awon eyan lo ti so emi won nu ninu ijamba ina ti oko ajepo kan fa ni opopona marose Eko si Ibadan
Opolopo awon eyan ti ku, ti opolopo awon oko ayokele ati dukia si ti sofo ninu ijamba ina ti oko ajepo kan fa ni opopona marose Eko si Ibadan ni osan oni. Gege bi atejade ti awon ti oro na se oju won so, won so wipe ori oke afara Otedola ni isele na ti sele, ti ko si si eni to le so ni pato, iye eyan to ti ku ninu isele na.
Awon eleyinju anu ati awon osise ile ise pana-pana ti wa bere si sise lori isele na.
Comments
Post a Comment