Awon agbebon ti pa Imamu agba kan ni ipinle Plateau


Awon agbebon kan ti yin ibon pa Imamu agba  Alhaji Abdullahi Abubakar  ni Bachi, ijoba ipinle Riyom ni ipinle Plateau. Gege bi atejade ti adari egbe Miyetti Allah Cattle Breeders Association in Nigeria (MACBAN), Alhaji Mato Ibrahim se, o fi han wipe oni iwa tutu ati olufe gbogbo eniyan ni ologbe na je.
Gege bi iwadi ti awon agbofinro se, won fi han wipe nkan bi ago mewa ale ni awon odaran na wole ti ologbe na, ti won si yin ibon pa. Awon agbofinro ti wa bere iwadi to peye lori oro na, won si ti bura lati mu awon to se asemase yi.

Comments