Awon eyan meji so emi won nu ninu ijamba oko kan to sele ni opopona marose Eko si Ibadan

Ijamba oko kan to sele ni osan ojo kokanlelogun osu kejo ni opopona marose Eko si Ibadan ni awon eyan meji ti so emi won nu.

Gege bi atejade ti oga agba ajo FRSC ni ipinle Ogun, ogbeni  Clement Oladele se, o so wipe nkan bi ago marun irole ni ijamba oko na sele nigba ti taya oko akero na be lori ere, eyi lo fa ti oko na fi gbe okiti ti opolopo awon eyan si farapa, ti meji ninu awon ero na si so emi won nu.
O so siwaju si wipe awon eleso abo ilu ati eleyin ju anu ti gbe oku awon meji na lo si ite igboku si, ti awon to si farapa si tin gba itoju ni ile iwosan Isara Hospital, ni ilu Ogere.

Ogbeni Clement wa fi anfani na ro awon awako lati sora loju popo, ki won si ma se itoju oko won ni ore-kore.

Comments