Awon agbofinro ti bere iwadi lori iku omidan Seun Ajila


Leyin iku omidan Seun Ajila, eni ti won fi ipa balo ti won si da emi re legbodo ni ojo kerin osu kewa ni ile re ni ilu Akure ni awon agbofinro ti bere iwadi lori oro na, won si ti mu afesona re Ebenezer Adejimola eni ti won fura si wipe oun lo se ise buruku na.

Ebenezer Adejimola omo ile iwe giga Adekunle Ajasin University Akungba Akoko ni won ti gbe lo ile ejo Magisiitrati to wa ni ipinle Ondo. Ile ejo na si ti sun igbejo siwaju di ojo kejilelogun odun 2019.

Comments