Awon eyan mesan lo so emi won nu ninu ijamba oko kan to waye ni opopona Eko si Ibadan

Ijamba oko kan to waye laarin oko ayokele Mercedes-Benz Marcopolo ati ojo ajagbe Iveco ni agbegbe Aseese ni opopona Eko si Ibadan ni iroyin fi to wa leti wipe awon eyan mesan ti so emi won nu.

Gege bi atejade ti oga agba ajo FRSC ni ipinle Ogun se, o so wipe awon eyan mejilelgoji lo wa ninu ijamba oko na sugbon awon mesan to so emi won nu. O so siwaju si wipe meje ninu awon mesan na lo je okunrin ti awon meji si je obirin. O wa fi ye awon akoroyin wipe won ti gbe oku awon to so emi won nu lo si ite igbokusi Olabisi Onabanjo University Teaching Hospital ni ipinle Ogun.

Comments