Gbajugbaja olorin takasufe orilede South Africa HHP ti ku

Ogbontarigi ati gbajugbaja odomode olorin takasufe ni orilede South Africa, ogbeni Jabulani Tsambo eni ti inagi re n'je HHP ti ku.

Oni, ojoru, ojo kerindinlogun osu yi ni odomodekunrin na pa ipo da. Idi iku ojiji arakunrin na lo si je kayefi fun gbogbo eniyan, sugbon awon molebi ati ololufe re ti fi idi isele buruku na mule.

Adura wa ni wipe ki Olorun fi orun ke ologbe na, ko si petu si awon molebi re lo'kan. Amin.

Comments