Ijoba ipinle Kano ti bere iwadi lori esun jibiti ti won fi kan Gomina Abdullahi Umar Ganduje

Leyin ti fidio amohun-maworan to fi han nibi ti Gomina ipinle Kano Abdullai Umar Ganduje tin gba riba lowo awon alabajosise ipinle na, to si ti fa rogbodiyan laarin gbogbo awon ololufe re ati awon omo orilede Nigeria lori ero ayelujara.

Ijoba ipinle na, ti wa se ifilole awon atopinpin meje kan lati bere iwadi to peye lori oro na. Ogbeni Labaran Abdul Madari lo mu aba iwadi na wa, latari oju esin ti fidio na ti mu wa si ipinle na ati paapa julo si ipo Gomina ipinle na.
 Ogbeni Baffa Babba Danagundi. bakana ro awon omo egbe igbimo asofin ni ipinle na lati se iwadi ki won to gbe Gomina na lo si ile ejo.

Comments