Ola ni eto isinku Adajo agba Idris Lebo Kutigi

Awon molebi adajo agba Idris Lebo Kutigi ti fi han wipe ola ojo ketalelogun osu kewa ni eto isinku ologbe na o waye.

Won o gbe oku adajo agba na wo orilede Nigeria lati orilede London ni nkan bi ago meji ola, be gege ni eto isinku na yo waye ni ola ode yi na.

Ite isinku Gudu Cemetery ni  ilu Abuja ni won o sin oku ologbe na si, ti eto adura Janazah o si waye ni National Mosque ni ilu Abuja.

Adura wa ni wipe ki Olorun te ologbe na si afefe ire. Amin.

Comments