O MA SE O! Oluko agba kan ni ipinle Benue gba emi ara re

Oluko agba ti oruko re n je Frank Onyezili ni ile eko giga Federal University of Agriculture in Makurdi (FUAM) ni iroyin fi to wa leti wipe o ti gba emi ara re.

Gege bi iwadi, ologbe Frank lo gbe majele je ninu ile re, to si ko atejise kan sile fun awon molebi re. Ninu atejise na, o fi han wipe awon molebi oun, iyawo ati omo to fi oun sile lo fa ti oun fi pinu lati gba emi ara oun.

Oga agba kan n ile iwe giga FUAM, arabirin Rosemary Waku fi idi oro yi mule, o si so siwaju si wipe awon ti kan si awon molebi ologbe na.

Comments