Iku Do'ro! Ogbontarigi sorosoro Tosyn Bucknor ti ku

Ibanuje ati kayefi nla lo je nigba ti iroyin iku ogbontarigi soror, arabirin Tosyn Bucknor to wa leti. Gege bi atejade ati afihan ti egbon  ologbe na arabirin Olufunke Bucknor Obruthese lori itakun ayelujara instagram, o je ko ye wa wipe oko arabirin na lo ba oku re ninu ile leyin igba to pada wole lati ibi ise re.

Iwadi fi ye wa siwaju si wipe omo odun metadinlogoji ni ologbe na je ki olojo to de, ti o si ba aisan aromolegun jajakadi ki iku to mu eni ire na lo.

Opolopo awon eyan lo ti wa fi ibanuje ati ikedun won han, ti won si ti fa ohun gbogbo le olorun lowo. Adura wa ni wipe ki Olorun te ologbe na si afefe ire. Amin.

Comments