Odomodebirin kan so emi re nu nigba to jana mo oko lenu ni ipinle Eko

Isele buruku kan sele ni ojo keresi ni opopona ilaje si Ajah ni ipinle Eko nigba ti oko ayokele kan gba odomodebirin   omo ile eko giga Olabisi Onabanjo ti oruko re nje Boluwatife Oyeleye ni ipinle Eko.
 Gege bi aheso ta gbo lenu awon ti oro na se oju won, won so wipe arabirin na lo ti ero igborin si eti, to si gbiyanju lati fona si odi keji lai mo wipe oko ayokele kan sa ere bo.
 Oko ayokele na lo gba omobirin na, ti o si salo lai boju weyin. Awon eleyinju anu gbiyanju lati gbe odomobirin na lo si ile iwosan sugbon epa o boro mo.

Comments