Isele buruku kan sele loni ni ile ifowopamo kan to wa ni ilu Calabar nigba ti oga olopa ton mojuto ile ifowopamo na yin ibon pa ogagun kan ti oruko re nje Val Monfort Sixtus .
Gege bi atejade ti agbenuso fun awon olopa ni ipinle cross river DSP Irene Ugbo se, o so wipe oga olopa na gbo ti ija n sele ni ita ile ifowopamo na, o si gbiyanju lati pari ija to besile na, sugbon o sesi yin ibon,ti ota ibon na si lo ya pa ogagun Sixtus.
Won gbiyanju lati dola emi ogagun na nigba ti won gbe lo si ile iwosan University of Calabar Teaching Hospital, UCTH. Sugbon ki won to gbe de ile iwosan na, epa o boro mo.
Iwadi to peye tiwa bere lori oro na. Adura wa ni wipe ki Olorun ma gba esu laaye lati lo wa. Amin
Comments
Post a Comment