Opolopo awon eyan lo ti so emi won nu ninu ikolu awon agbebon to waye ni ipinle Zamfara

Awon eyan mewa o kere tan lo ti so emi won nu ninu ikolu ti awon agbebon kan se ni abule Dogon ni ijoba ipinle Tsafe, ati Birnin ni agbegbeShinkafi ni ipinle Zamfara.

Gege bi atejade ti awon ti oro na se oju won so, won so wipe awon agbebon na lo ya bo mosalasi to wa ni abule na nibi ti won tin kirun ti won si pa Mallam Ibrahim Dan Kurya, ni kete ti awon eyan ri eleyi ni won tuka, ti won si sa asala fun emi won sugbon ni se ni awon agbebon na bere sini yin ibon ti won si pa awon eyan mewa.

Awon agbofinro ton soju ipinle na ti fi idi ikolu na mule, won si ti pinu lati mu awon janduku na, ki won si fi oju ba ile ejo.

Comments