Owo awon agbofinro ti ba ilu mo'ka olorin Small Doctor

Owo awon agbofinro ti ba odomodekunrin olorin small doctor leyin igba ti oun ati awon akegbe re gbiyanju lati yin oga olopa kan ni ibon ni ipinle Eko.

Gege bi atejade ti awon ti oro na se oju won se, won so wipe Small Doctor ati awon akegbe re meta miran lo wa ninu oko ayokele kan, ti oga olopa kan si da won duro lati ye oko won wo, sugbon kaka ki won duro, se ni won so fun olopa na wipe to ba ko lati kuro lo'na, awon yo yin ni ibon.

Ni kete ti eleyi sele ni awon oga olopa na fi to awon agbofinro egbe re leti ti won si mu Small Doctor ati awon akegbe re lo si ago olopa fun iforo wani lenu wo ati iwadi to peye.

Comments