Awon ọgọ́fà adajo lo ti gbaradi lati soju adajo agba Walter Samuel Nkanu Onnoghen ni ile ejo

Leyin ti ijoba apapo fi esun kan adajo agba fun orilede Nigeria  Walter Samuel Nkanu Onnoghen ti won si ti setan lati gbe lo fi oju ba ile ejo ni aro ola ojo kerinla osu kini odun 2019.

Opolopo awon adajo akegbe re to to ogofa lo ti setan, ti won si ti gbaradi lati lo soju adajo agba na ni ile ejo. Gege bi atejade ti adajo Sebastine Hon ba iwe irohin Daily Trust se ni aro ojo abameta, o fi idi re mule, o si fi han wipe ise ti bere ni perewu lori ejo na.

Comments