Ile ejo ti fun Senito Dino Melaye ni anfani lati lo mojuto eto ilera re

Ile ejo agba orilede Nigeria ti fun Senito Dino Melaye eni to ti wa lakata awon agbofinro fun nkan bi ose kan ni anfani lati lo mojuto eto ilera re.

 Dino Melaye, eni to daku ni ojo kerin osu yi ni ilu Abuja nigba ti awon agbofinro lo mu gege bi ile ejo ti pa won lase, lo ti wa lori idubule aisan lati ojo na. Ile ejo bakana ti wa pinu lati fun ni anfani lati lo gba itoju to peye, eleyi ti yo fun ni anfani lati jejo esun ti won fi kan wipe o gbiyanju lati pa oga olopa kan.

Comments