Ile ejo ti sun igbejo adajo agba Walter Onnoghen si ojo kejilelogun osu yi



Igbejo to waye laarin ijoba apapo ati adajo agba Walter Onnoghen ni ile ejo ti sun siwaju di ojo
 kejilelogun osu kini odun yi.

Eyi waye leyin opolopo atotonu ati iforojomitoro-oro to waye laarin olugbejo fun ijoba apapo Aliyu Umar SAN ati olugbejo fun eni ti won fi esun kan adajo agba Walter Onnoghen. Olugbejo fun ijoba so wipe ko si idi ti adajo agba na o se ye ko wa ni ile ejo na, wipe iwa aibikita fun ofin ati iwa ijora eni loju gba ni iwa na.

Eyi lo mu alakoso ile ejo na Adajo agba Umar Danladi sun igbejo na si ojo kejilelogun osu yi.

Comments