Owo awon agbofinro ti ba arakunrin to pa Iyawo ati awon omo re ni ipinle Edo

Arakunrin omo odun marunlelọgbọn kan ti oruko re nje Uwaila Idehen eni to yin ibon pa iyawo re ati awon omokunrin re meji ni agbegbe Ovbioge ni ijoba ipinle Ovia North ni ipinle Edo.

Gege bi atejade ti awon aradugbo se, won fi han wipe arakunrin na leyin igba to ni gbolohun aso kekere kan pelu iyawo re lo gbe ibon sakabula wole, to si yin ibon na pa iyawo re ati awon omokunrin re mejeji. 

Nigba ti owo awon agbofinro te arakunrin na, o so fun won wipe bi isele na se sele ko ye ohun rara, wipe oun o si mu oti yo. O so siwaju si wipe oun ni ife iyawo oun gidi-gidi, ati wipe ise esu ni isele to sele laarin awon mejeji.

Comments