Awon eyan merindiladorin lo ti so emi won nu ni ilu Kaduna latari atotonu eto idibo

Okeretan awon eyan merindinladorin lo ti so emi won nu ni ilu Kaduna latari atotonu eto idibo Aare orilede Nigeria to ye ko waye ni ola.

Ijoba ipinle Kaduna lo fi idi oro na mule pelu atejade kan to ti owo ogbeni Samuel Aruwan eni to je agbenuso fun gomina ipinle na Nasir El-Rufai, ti won si ti pinu lati wadi awon koloransi to se ise ibi na.

O so siwaju si wipe ki gbogbo awon omo ipinle Kaduna ati gbogbo omo orilede Nigeria lapapo gbiyanju lati lodi si itajesile nitori eto idibo, o ro won lati gba alafia laye, ki won si yan adari rere ti yo gbe orilede Nigeria de ebute yinyanju.

Comments