Gbajugbaja oserekunrin Jussie Smollett ti wa ni atimole awon olopa

Oserekunrin Jussie Smollett eni ti awon agbofinro tin wa fun esun pipa iro mo ara eni ati eke sise ni owo awon agbofinro ti ba, to si ti wa ni atimole awon olopa.

Iwadi fi han wipe arakunrin na lo da bi ogbon alumokoroyi lati san owo fun awon tegbon-taburo kan lati orilede Nigeria ti oruko won nje Abel ati Ola Osundairo lati wa fi iya je oun, ki awon ololufe re le ro boya lotoo ni won na. Kayefi ni eleyi je fun awon ololufe re nigba ti asiri re tu, ti ko si ye eni keni rara idi ti arakunrin na o fi da iru ogbon rada-rada na.

Oga olopa ton mojuto oro na ti wa fi da gbogbo eyan loju wipe laipe-lai jina, ijiya to ye fun iru esun na yo je odomodekunrin osere na.

Comments