Opolopo awon eyan lo tun ti farapa nigba ti ile kan tun da-wo ni ilu Eko

Leyin bi ose kan pere ti ile wo pa awon omo ile iwe kan ni agbegbe Ita Faaji ni ilu Eko, irohin ti fi to wa leti wipe opolopo awon eyan lo tun ti farapa nigba ti ibudo miran tun wo lule ni agbegbe Egerton Square Alakoro ni  Lagos Island ni ipinle Eko.

Awon aradugbo ati awon eleso abo ilu ti wa bere akitiyan lati dola emi awon to wa ninu awoku ile na. Ijoba ipinle Eko bakana ti pinu lati gbogun ti isele ijamba ile wiwo.

Comments