Owo ajo EFCC ti ba arakunrin Anieka Udoh fun esun jibiti


Owo awon osise ajo EFCC ti ba arakunrin kan osise ile ifowopamo Ecobank Plc ti oruku re nje Anieka Udoh fun esun jibiti owo to to millionu mesan naira. 

Ajo na lo ti gbe arakunrin na lo lati fi oju ba ile ejo agba kan to wa ni ipinle Eko ni ojo keje osu yi. Adajo ton da ejo na adajo agba Saliu Seidu  ti fi esun elenu marrun kan olugbejo na, o si ti fun ajo EFCC ni ase lati se iwadi to peye lori oro na, ki won si fi idi ododo mule.

Adajo agba Saliu Seidu bakana ti sun igbejo na siwaju si ojo kejila osu keta odun yi.

Comments