EFCC e ba mi gbe owo mi, abi kilo sele gan-gan? - Arabirin Patience Jonathan lo so be

Iyawo Aare orilede Nigeria nigbakanri, arabirin Patience Jonathan ti ke gbajari fun ile ejo agba kan ni ilu Abuja lati kilo fun ajo EFCC ki won da owo oun pada. O so siwaju si wipe nigbati ko si enikeni to fi esun kan oun wipe oun ji owo won, ki won ya tete kilo fun ajo EFCC ki won da  $5.7m ati N2.4bn oun ti won gbesele pada ni kia-kia.

Agbejoro fun arabirin na so wipe awon owo ti awon osise ajo EFCC na gbesele je awon ebun ti oun ri gba lati awon eyan nigba ti oko oun si je Aare orilede Nigeria. O wa ro adajo agba na wipe ki won tete sise lori bi ajo EFCC o se da awon owo na pada lai pe, lai jina.

Comments