Okere tan awon eyan merin ni irohin ti to wa leti wipe won ti so emi won nu ninu ijamba ina kan to waye nigbati afefe idana (gas) kan gba ina je ni ile epo Total kan to wa ni agbegbe Sabon Tacha ni ilu Kaduna ni nkan bi ago kan osan oni.
Arakunrin Philip Kambi eni ti isele na se oju re sugbon ti ori ko yo ninu ijamba na so wipe
Oun sese ge irun tan ni nigbati oun gba iro kan to dun gbam, ti ina si gbi yika gbogbo adugbo na.
O so siwaju si wipe opolopo awon eyan lo fi ara pa yana-yana ti oku si sun lo bi eru.
Awon alamojuto abo ilu tiwa lo si ibi isele na, lati to pinpin isele na, ki won si mo idi ti ijamba na fi waye. Won ti gbe oku awon ologbe lo si iteigbokusi, won si ti ko awon to farapa lo si ile iwosan.
Comments
Post a Comment