Awon agbebon kan ti ji omo oga agba ile eko giga Unifasiti Ahmadu Bello gbe


Awon agbebon kan ti ji arabirin Maryam Abdullahi Mustapha eni to je omobirin oga agba ile eko giga Unifasiti Ahmadu Bello gbe. Isele ojo buruku esu gbomi mu na lo sele ni ojo keje osu yi nigba ti awon agbebon na ya wonu ile ojogbon Abdullahi Mustapha ti won si gbe omobirin na lo. 

Awon ti oro na se oju won so wipe ni nkan bi ago mokanla abo ale ni awon agbebon na ya bo ile na, ti won si yin ibon fun arakunrin to so ogba ile na, ki won to wa gbe arabirin Maryam na gbe lo.

Awon agbofinro ti bere iwadi to peye lori oro na, won si ti pinu lati tu isu de isale ikoko oro na, lati ri wipe awon koloransi na fi imu danrin.

Comments