Aworan nibi eto isinku ojise Olorun ti ijo Katoliki mimo ti awon ajinigbe pa ni ipinle Kaduna



 Ibanuje ati omije loju ni awon molebi, ore ati gbogbo ijo Katoliki mimo to wa ni ipinle Sokoto fi se eto isinku fun ojise olorun omo odun mejidinlogun ti oruko re nje Michael Nnadi ti awon ajinigbe pa ni ilu Kaduna.

Bisobu agba ti ipinle sokoto Mathew Kukah ati bisobu agba Mathew Ndagoso lo peju sibi eto isinku na, ti won si ro awon omo leyin kristi lati di igbagbo won mu sin-sin paapa julo pelu gbogbo isele ija elesin mesin ton sele kakiri orilede Nigeria. 

O wa ro ijoba apapo lati moju to eto abo ni orilede yi, ki won si gbiyanju lati fi opin si ipaniyan ojojumo ton sele kaakiri, paapa julo si awon omo leyin kristi.






Comments