Àwon òdómodékùnrin meta kan tí àwon agbófinró fura sí pàdánù èmí won nínú ijamba okò tó wáyé ní ìlú Òsogbo
Ojo buruku esu gbomi mu ni oro isele kan to sele ni ilu Osogbo ni irole ojo karundinlogun osu kesan odun yi, nigbati awon agbofinro fi oko won le awon odomodekunrin kan ti won fura si gege bi onijibiti lori ero ayelujara (Yahoo-Yahoo).
Awon agbofinron na ni irohin fi to wa leti wipe won le awon odomodekunrin meta na titi oko won fi fori sole, ti ijamba oko na si gba emi awon meteta lesekese. Awon olugbe ilu Osogbo ti wa bere sini fi ibinu won han, ti won si ti gbe oku awon ologbe na lo si iwaju ile Gomina ipinle na.
Gomina Oyetola wayi, ti wa fi won lokan bale, o si ki won ku araferakun, osi fi da gbogbo awon omo ipinle Osun loju wipe lai pe, awon agbofinro na o fi oju ba ida ofin
Comments
Post a Comment