Ojú ti Elégàn: Messi ti gba Ife eye àgbáyé fún orilede Agentina

 

Idunu ati ayo ni awon ololufe egbe agbaboolu Agentina paapa julo awon ololufe agbaboolu Messi fi pari idije World Cup to waye loni ni orilede Qatar.

Oju ogun le nigba ti idije ifesewonse na, nlo nigba ti won koju orilede Faranse, ti won si bori won. Idije koju simi kin gba si o ni won fi yanju idije na. Awon omo egbe agbaboolu Agentina lo koko gba omi ayo meji wole, leyin na ni iko egbe agbaboolu Faranse da omi ayo meji na pada.

Oju ti gbogbo awon ton pegan Messi, won si kari bonu bi adiye ti ojo pa.

Comments