Egbe agbaboolu Arsenal na Chelsea lati agba ife eye F.A.








Egbe agbaboolu Arsenal ti gba ami eye egbe agbaboolu to se orire junigba ti won gbo omi ewuro si egbeagbaboolu Chelsea loju lati gba ife eye F.A ni irole ana. Alex Sanchez lo koko gba omi ayo kan wole fun iko egbe agbaboolu Arsenal, leyin na  ni Diego Coasta da ikan pada fun iko egbe agbaboolu Chelsea. Ko pe ko jina ni Aaron Ramsey wa fi oba le fun iko egbe agbaboolu Arsenal.
Idunu ati ayo ni awon ololufe egbe agbaboolu Arsenal fi lo si ile won lana, ti ironu si dori agba Chelsea kodo.

Comments