Owo awon agbofinro to wa ni opopona Aliade si Otukpo te arakunrin omo ile eko giga ti ipinle Benue kan ogbeni Victor Ogbu, ti won si ri ibon ilewo kan ati opolopo ota ibon lowo re. Omokunrin na lo jewo nigba ti won fi oro wa lenu wo wipe elegbe okunkun ni ohun, ti ohun si man fi ibon oun jale pelu awon akegbe ohun to ku.
Oruko awon akegbe re to ku ni ti; a. Zahemen Avaa
b. Ebenezer Ikyereve
c. Teryima Orkeghen
d. Lubem Torhile.
Iwadi to peye tin lo lori oro won, ti oga olopa si ti pinu lati gbe oro won lo si ile ejo.



Comments
Post a Comment