Opolopo dukia lo jona ninu ijamba ina to sele ni ile eko giga Unizik

Yara ikeko awon akeko irohin ni ile eko giga Nnamdi Azikiwe University, ni ilu Awka, ipinle Anambra lo jona,ti opopolopo dukia si sofo. 

Gege bi atejade ti awon osise ile eko giga na se, won fi han wipe aro kutukutu ojo aiku ni isele ibi na sele. Iwadi to peye si ti bere lori bi won o se mo nkan to fa sababi ijamba ina na.
Oluko agba kan ni ile eko giga na Francis Okeke so siwaju si wipe akitiyan lati tun yara ikeko na se ti bere, o fi han wipe ile oba to jona, ewa lo bu si.

Comments