Oma se o, omo ile iwe giga Uniben kan pa iya re nitori owo ounje.

Omode kunrin kan omo odun mejilelogoji ti oruko re nje Caleb Obasogie pa iya re arabirin Josephine Igbineweka ni ilu Benin ipinle Edo nitori owo ounje.
 Gege bi atejade ti awon ti oro na se fun awon oni iwe iroyin, won so wipe ogbeni Caleb eni ti iya re n ta oti, fi igi fo ori iya re nitoripe o bere owo lowo iya re lati lo si ile iwe, igba ti arabirin na ko lati fun ni arakunrin na fo ori iya re,tosi fi igo la ikun re lati ko ifun re jade.
  Awon aradugbo to jade lati ran iya na lowo, lo ri ifun arabirin na lowo omo re ti won si sure pe awon agbofinro.
    Oga olopa ton soju ipinle Edo DSP Moses Nkombe fi idi oro yi mule, o si so wipe awon ti fi odaran na si ago olopa won, ti o si ti setan lati fi oju ba ile ejo.

Comments